Orin Solomoni 6:10
Song of Songs 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
Song of Songs 6:10 in English
Song of Songs 6:10 · Berean Standard Bible
Who is this who shines like the dawn, as fair as the moon, as bright as the sun, as majestic as the stars in procession?
Context
8Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,
àti ọgọ́rin àlè,
àti àwọn wúńdíá láìníye. 9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,
ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,
ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún
àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un. 10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,
tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,
tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun? 11Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi
láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,
láti rí i bí àjàrà rúwé,
tàbí bí pomegiranate ti rudi. 12Kí èmi tó mọ̀,
àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.