Native Bible

Song of Songs 6:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.

Song of Songs 6:9 in English

Song of Songs 6:9 · Berean Standard Bible

but my dove, my perfect one, is unique, the favorite of the mother who bore her. The maidens see her and call her blessed; the queens and concubines sing her praises.

Context

7Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pomegiranate. 8Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúńdíá láìníye. 9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un. 10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun? 11Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pomegiranate ti rudi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.