Native Bible

Song of Songs 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

Song of Songs 4:7 in English

Song of Songs 4:7 · Berean Standard Bible

You are altogether beautiful, my darling; in you there is no flaw.

Context

5Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì. 6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí. 7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. 8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. 9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.