Native Bible

Song of Songs 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

Song of Songs 4:8 in English

Song of Songs 4:8 · Berean Standard Bible

Come with me from Lebanon, my bride, come with me from Lebanon! Descend * from the peak of Amana, from the summits of Senir and Hermon, from the dens of the lions, from the mountains of the leopards.

Context

6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí. 7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. 8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. 9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. 10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.