Orin Solomoni 4:10
Song of Songs 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!
Song of Songs 4:10 in English
Song of Songs 4:10 · Berean Standard Bible
How delightful is your love, my sister, my bride! Your love is much better than wine, and the fragrance of your perfume than all spices.
Context
8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,
ki a lọ kúrò ní Lebanoni.
Àwa wò láti orí òkè Amana,
láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,
láti ibi ihò àwọn kìnnìún,
láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. 9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìwọ ti gba ọkàn mi
pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,
pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. 10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!
Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,
òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! 11Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;
wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.
Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni. 12Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.