Orin Solomoni 4:9
Song of Songs 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.
Song of Songs 4:9 in English
Song of Songs 4:9 · Berean Standard Bible
You have captured my heart, my sister, my bride; you have stolen my heart with one glance of your eyes, with one jewel of your neck.
Context
7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;
kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. 8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,
ki a lọ kúrò ní Lebanoni.
Àwa wò láti orí òkè Amana,
láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,
láti ibi ihò àwọn kìnnìún,
láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. 9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìwọ ti gba ọkàn mi
pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,
pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. 10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!
Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,
òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! 11Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;
wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.
Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.