Native Bible

Song of Songs 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é.

Song of Songs 3:9 in English

Song of Songs 3:9 · Berean Standard Bible

King Solomon has made his carriage out of the timber of Lebanon.

Context

7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli, 8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru 9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é. 10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀, o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí. “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.” 11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.