Native Bible

Song of Songs 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli,

Song of Songs 3:7 in English

Song of Songs 3:7 · Berean Standard Bible

Behold, it is Solomon’s carriage,* escorted by sixty of the mightiest men of Israel.

Context

5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò? 7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli, 8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru 9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.