Native Bible

Song of Songs 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?

Song of Songs 3:6 in English

Song of Songs 3:6 · Berean Standard Bible

Who is this coming up from the wilderness like a column of smoke, scented with myrrh and frankincense from all the spices of the merchant?

Context

4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi. 5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò? 7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli, 8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.