Orin Solomoni 3:4
Song of Songs 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.
Song of Songs 3:4 in English
Song of Songs 3:4 · Berean Standard Bible
I had just passed them when I found the one I love. I held him and would not let go until I had brought him to my mother’s house, to the chamber of the one who conceived me.
Context
2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,
ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;
èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i. 3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” 4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀
ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ
títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,
sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi. 5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá
bí ọ̀wọ̀n èéfín
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára
pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.