Native Bible

Song of Songs 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

Song of Songs 3:8 in English

Song of Songs 3:8 · Berean Standard Bible

All are skilled with the sword, experienced in warfare. Each has his sword at his side prepared for the terror of the night.

Context

6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò? 7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli, 8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru 9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é. 10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀, o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí. “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.