Orin Solomoni 2:11
Song of Songs 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
Song of Songs 2:11 in English
Song of Songs 2:11 · Berean Standard Bible
For now the winter is past; the rain is over and gone.
Context
9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín.
Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà. 10Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi. 11Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ. 12Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa. 13Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn.
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi,
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.