Native Bible

Song of Songs 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn. Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi, Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

Song of Songs 2:13 in English

Song of Songs 2:13 · Berean Standard Bible

The fig tree ripens its figs; the blossoming vines spread their fragrance. Arise, come away, my darling; come away with me, my beautiful one.”

Context

11Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ. 12Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa. 13Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn. Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi, Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.” 14Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà. 15Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.