Native Bible

Song of Songs 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.

Song of Songs 2:15 in English

Song of Songs 2:15 · Berean Standard Bible

Catch for us the foxes— the little foxes that ruin the vineyards— for our vineyards are in bloom.

Context

13Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn. Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi, Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.” 14Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà. 15Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná. 16Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì. 17Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Beteri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.