Native Bible

Song of Songs 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.

Song of Songs 2:9 in English

Song of Songs 2:9 · Berean Standard Bible

My beloved is like a gazelle or a young stag. Look, he stands behind our wall, gazing through the windows, peering through the lattice.

Context

7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 8Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. 9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà. 10Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi. 11Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.