Native Bible

Song of Songs 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

Song of Songs 2:7 in English

Song of Songs 2:7 · Berean Standard Bible

O daughters of Jerusalem, I adjure you by the gazelles and does of the field: Do not arouse or awaken love until the time is right.

Context

5Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èso ápù tù mi lára nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. 6Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra. 7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 8Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. 9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.