Orin Solomoni 2:5
Song of Songs 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èso ápù tù mi lára nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
Song of Songs 2:5 in English
Song of Songs 2:5 · Berean Standard Bible
Sustain me with raisins; refresh me with apples, for I am faint with love.
Context
3Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,
ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin.
Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,
èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu. 4Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,
ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. 5Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.
Fi èso ápù tù mi lára
nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. 6Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi
ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra. 7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú
kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.