Romu 9:25
Romans 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”
Romans 9:25 in English
Romans 9:25 · Berean Standard Bible
As He says in Hosea: “I will call them ‘My People’ who are not My people, and I will call her ‘My Beloved’ who is not My beloved,”*
Context
23Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. 24Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,
“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’,
àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ” 26Yóò sì ṣe,
“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ” 27Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé:
“Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun,
apá kan ni ó gbàlà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.