Romu 9:24
Romans 9:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú?
Romans 9:24 in English
Romans 9:24 · Berean Standard Bible
including us, whom He has called not only from the Jews, but also from the Gentiles?
Context
22Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun. 23Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. 24Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,
“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’,
àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ” 26Yóò sì ṣe,
“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.