Native Bible

Romans 9:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

Romans 9:26 in English

Romans 9:26 · Berean Standard Bible

and, “It will happen that in the very place where it was said to them, ‘You are not My people,’ they will be called ‘sons of the living God.’”*

Context

24Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ” 26Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ” 27Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà. 28Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.