Native Bible

Romans 9:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

Romans 9:28 in English

Romans 9:28 · Berean Standard Bible

For the Lord will carry out His sentence on the earth thoroughly and decisively.”*

Context

26Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ” 27Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà. 28Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.” 29Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.” 30Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.