Native Bible

Romans 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”

Romans 9:29 in English

Romans 9:29 · Berean Standard Bible

It is just as Isaiah foretold: “Unless the Lord of Hosts had left us descendants, we would have become like Sodom, we would have resembled Gomorrah.”*

Context

27Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà. 28Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.” 29Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.” 30Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. 31Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.