Native Bible

Romans 9:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo.

Romans 9:31 in English

Romans 9:31 · Berean Standard Bible

but Israel, who pursued a law of righteousness, has not attained it.

Context

29Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.” 30Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. 31Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. 32Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni. 33Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.