Native Bible

Romans 9:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo.

Romans 9:23 in English

Romans 9:23 · Berean Standard Bible

What if He did this to make the riches of His glory known to the vessels of His mercy, whom He prepared in advance for glory—

Context

21Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá? 22Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun. 23Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. 24Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.