Romu 10:18
Romans 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”
Romans 10:18 in English
Romans 10:18 · Berean Standard Bible
But I ask, did they not hear? Indeed they did: “Their voice has gone out into all the earth, their words to the ends of the world.”*
Context
16Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” 17Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:
“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,
àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.” 19Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé,
“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.
Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.” 20Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé,
“Àwọn tí kò wá mi rí mi;
Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.