Native Bible

Romans 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé, “Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú. Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”

Romans 10:19 in English

Romans 10:19 · Berean Standard Bible

I ask instead, did Israel not understand? First, Moses says: “I will make you jealous by those who are not a nation; I will make you angry by a nation without understanding.”*

Context

17Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.” 19Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé, “Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú. Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.” 20Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé, “Àwọn tí kò wá mi rí mi; Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.” 21Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé, “Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.