Romu 10:17
Romans 10:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Romans 10:17 in English
Romans 10:17 · Berean Standard Bible
Consequently, faith comes by hearing, and hearing by the word of Christ.
Context
15Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!” 16Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” 17Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:
“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,
àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.” 19Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé,
“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.
Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.