Native Bible

Psalms 69:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

Psalms 69:20 in English

Psalms 69:20 · Berean Standard Bible

Insults have broken my heart, and I am in despair. I looked for sympathy, but there was none, for comforters, but I found no one.

Context

18Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là; rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi. 19Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá; gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ. 20Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan. 21Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi, àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi. 22Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.