Native Bible

Psalms 69:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

Psalms 69:2 in English

Psalms 69:2 · Berean Standard Bible

I have sunk into the miry depths, where there is no footing; I have drifted into deep waters, where the flood engulfs me.

Context

1Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi. 2Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀. 3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi. 4Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi lọ, púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run. A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.