Saamu 69:3
Psalms 69:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
Psalms 69:3 in English
Psalms 69:3 · Berean Standard Bible
I am weary from my crying; my throat is parched. My eyes fail, looking for my God.
Context
1Gbà mí, Ọlọ́run,
nítorí omi ti kún dé ọrùn mi. 2Mo ń rì nínú irà jíjìn,
níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀. 3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi. 4Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
wọ́n ju irun orí mi lọ,
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
àwọn tí ń wá láti pa mí run.
A fi ipá mú mi
láti san ohun tí èmi kò jí. 5Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.