Saamu 69:5
Psalms 69:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
Psalms 69:5 in English
Psalms 69:5 · Berean Standard Bible
You know my folly, O God, and my guilt is not hidden from You.
Context
3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi. 4Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
wọ́n ju irun orí mi lọ,
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
àwọn tí ń wá láti pa mí run.
A fi ipá mú mi
láti san ohun tí èmi kò jí. 5Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ. 6Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;
má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,
Ọlọ́run Israẹli. 7Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
ìtìjú sì bo ojú mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.