Saamu 57:3
Psalms 57:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
Psalms 57:3 in English
Psalms 57:3 · Berean Standard Bible
He reaches down from heaven and saves me; He rebukes those who trample me. Selah God sends forth His loving devotion and His truth.
Context
1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
títí tí ewu yóò fi kọjá lọ. 2Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi. 3Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde. 4Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú. 5Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.