Native Bible

Psalms 57:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

Psalms 57:4 in English

Psalms 57:4 · Berean Standard Bible

My soul is among the lions; I lie down with ravenous beasts— with men whose teeth are spears and arrows, whose tongues are sharp swords.

Context

2Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi. 3Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde. 4Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú. 5Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ. 6Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú, wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.