Native Bible

Psalms 57:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.

Psalms 57:2 in English

Psalms 57:2 · Berean Standard Bible

I cry out to God Most High,* to God who fulfills His purpose for me.

Context

1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ. 2Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi. 3Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde. 4Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.