Native Bible

Psalms 18:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

Psalms 18:7 in English

Psalms 18:7 · Berean Standard Bible

Then the earth shook and quaked, and the foundations of the mountains trembled; they were shaken because He burned with anger.

Context

5Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 6Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀. 7Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú. 8Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. 9Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.