Native Bible

Psalms 18:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

Psalms 18:5 in English

Psalms 18:5 · Berean Standard Bible

The cords of Sheol entangled me; the snares of death confronted me.

Context

3Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi. 4Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. 5Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 6Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀. 7Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.