Saamu 18:6
Psalms 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
Psalms 18:6 in English
Psalms 18:6 · Berean Standard Bible
In my distress I called upon the LORD; I cried to my God for help. From His temple He heard my voice, and my cry for His help reached His ears.
Context
4Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. 5Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 6Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀. 7Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú. 8Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.