Saamu 129
Psalms 129 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá,”
jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí; 2“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá;
síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi. 3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
wọ́n sì la aporo wọn gígùn. 4Olódodo ni Olúwa:
ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.” 5Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà. 6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè, 7èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀. 8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.