Saamu 128
Psalms 128 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ. 3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká. 4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
tí ó bẹ̀rù Olúwa. 5Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo. 6Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.