Native Bible

Psalms 128:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

Psalms 128:3 in English

Psalms 128:3 · Berean Standard Bible

Your wife will be like a fruitful vine flourishing within your house, your sons like olive shoots sitting around your table.

Context

1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ. 3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká. 4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù Olúwa. 5Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.