Native Bible

Proverbs 29:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

Proverbs 29:11 in English

Proverbs 29:11 · Berean Standard Bible

A fool vents all his anger, but a wise man holds it back.

Context

9Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà. 10Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo. 11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu. 12Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀. 13Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.