Òwe 29
Proverbs 29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí
yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. 2Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀
nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra. 3Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀
ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́. 4Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,
ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀. 5Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀
ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀. 6Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀
ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀. 7Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó. 8Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò. 9Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n
aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà. 10Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin
wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo. 11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu. 12Bí olórí bá fetí sí irọ́,
gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀. 13Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,
Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran. 14Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́
ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo. 15Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n
ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀. 16Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀
ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn. 17Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà
yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ. 18Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,
ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́. 19A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́
bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i. 20Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?
Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ. 21Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré
yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn. 22Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,
onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀. 23Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀
ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì. 24Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,
ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn. 25Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu. 26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,
ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo. 27Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:
ènìyàn búburú kórìíra olódodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.