Native Bible

Proverbs 29:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

Proverbs 29:10 in English

Proverbs 29:10 · Berean Standard Bible

Men of bloodshed hate a blameless man, but the upright care for his life.*

Context

8Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò. 9Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà. 10Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo. 11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu. 12Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.