Native Bible

Proverbs 29:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

Proverbs 29:13 in English

Proverbs 29:13 · Berean Standard Bible

The poor man and the oppressor have this in common: The LORD gives light to the eyes of both.

Context

11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu. 12Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀. 13Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran. 14Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo. 15Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.