Òwe 16
Proverbs 16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn
ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá. 2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn. 3Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́,
èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe. 4Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́
kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú. 5Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀
mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà. 6Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀
nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi. 7Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,
yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà. 8Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo
ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ. 9Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀
ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀. 10Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i
ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké. 11Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀. 12Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́
nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀. 13Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,
wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́. 14Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú. 15Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;
ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò. 16Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ
àti láti yan òye dípò o fàdákà! 17Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,
ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀. 18Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,
agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú. 19Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú
jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga. 20Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,
ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa. 21Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye
ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú. 22Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,
ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n. 23Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀
ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà. 24Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin
ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun. 25Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn
ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú. 26Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀;
nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ. 27Ènìyàn búburú ń pète
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni. 28Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀
olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà. 29Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀
ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára. 30Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;
ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú. 31Adé ògo ni ewú orí jẹ́,
ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀. 32Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,
ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ. 33A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,
ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.