Native Bible

Proverbs 16:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.

Proverbs 16:23 in English

Proverbs 16:23 · Berean Standard Bible

The heart of the wise man instructs his mouth and adds persuasiveness to his lips.

Context

21Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú. 22Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n. 23Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà. 24Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun. 25Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.