Native Bible

Proverbs 16:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

Proverbs 16:4 in English

Proverbs 16:4 · Berean Standard Bible

The LORD has made everything for His purpose— even the wicked for the day of disaster.

Context

2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn. 3Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́, èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe. 4Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú. 5Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà. 6Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.