Native Bible

Proverbs 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.

Proverbs 16:7 in English

Proverbs 16:7 · Berean Standard Bible

When a man’s ways please the LORD, He makes even the man’s enemies live at peace with him.

Context

5Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà. 6Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi. 7Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà. 8Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ. 9Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.