Numeri 3:30
Numbers 3:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli.
Numbers 3:30 in English
Numbers 3:30 · Berean Standard Bible
and the leader of the families of the Kohathites was Elizaphan * son of Uzziel.
Context
28Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ta (8,600),
tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́. 29Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́. 30Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli. 31Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn. 32Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.