Native Bible

Numbers 3:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

Numbers 3:32 in English

Numbers 3:32 · Berean Standard Bible

The chief of the leaders of the Levites was Eleazar son of Aaron the priest; he oversaw those responsible for the duties of the sanctuary.

Context

30Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli. 31Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn. 32Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́. 33Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari. 34Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.